damnlyrics.com

Jesu, Mo Wa S'odo Re

Jesu mo wa sodo Re

1.f JESU mo wa sodo Re,

Je ki nle ma to O lehin

Bi 'ni mi gbogbo po si

Ti ero mi gbogbo soji.

Egbe: E yin logo, eyin Mimo

E f'ope fun Baba loke

Da wa si l'egbe Serafu,

Ni kehin gba okan wa la.

2.mf Keferi, Imale, e wa

Onigbagbo, ma kalo

K'a jo yin Olorun wa,

K'a le d'ade ni 'kehin.

Egbe: E yin logo, etc

3.mf A dupe lowo Olorun

T'o fi Jesu Kristi fun wa

Lati ra araiye pada,

Lowo ese at'Esu.

Egbe: E yin logo, etc

4.mf Egbe Serafu damure

Egbe Kerubu kun f'adura

Olugbala yio gba wa la

Oluwosan yio wo wa san.

Egbe: E yin logo, etc

8. Nigbati 'pe kehin ba dun

Jesu y'o ko wa de Kenaani,

Je ka l'ayo lodo Re

Fi wa s'agbala itura.

Egbe: E yin logo, etc

9. E f'ogo fun Baba loke

E f'ofo fun Omo pelu

E f'ogo fun Emi Mimo

Metalokan lope ye fun.

Egbe: E yin logo, etc Amin

Enjoy the lyrics !!!