damnlyrics.com

Jesu Oluwa Oba mi

JESU OLUWA OBA MI

1. Jesu Oluwa Oba mi

Gbohun mi nigbati mo npe

Gbohun mi lati 'bugbe Re

Ro 'jo ore - ofe sile.

Chorus: Oluwa mi mo feran Re

Je ki nle ma feran Re si

Oluwa mi, mo feran Re

Je ki nle ma feran Re si.

2. Jesu mo ti jafara ju

Nko se le fe O bo ti ye

Emi o se le gbogo Re ga

Ati ewa oruko Re.

3. Jesu ki lo ri ninu mi

Ti 'fe naa fi po to bayi

Ore Re si mi ti po to

O ta gbogbo ero mi yo.

4. Jesu 'wo o je orin mi

Tire laya at'okan mi

Tire ni gbogbo emi mi

Olugbala 'wo ni temi.

Enjoy the lyrics !!!