damnlyrics.com

Wa, Ma Sise

Wa, ma sise

1. Wa, ma sise

Tani gbodo s’ole ninu oko

Gbati gbogbo enia nkore jo

Kaluku ni Baba pase fun pe

“Sise loni”

2. Wa, ma sise

Gba ‘pe giga ti angeli ko ni

Mu ‘hinrere to t’agba t’ewe lo

“Ra ‘gba pada wawa akoko lo

Ile su tan.

3. Wa, ma sise

Oko po alagbase ko si to

A ni’bi titun gba a ni ‘po ro;

Ohun ona jijin, ati ‘tosi

Nkigbe pe wa

4. Wa, ma sise

Le ‘yemeji on aigbagbo jinna

Ko s’alailera ti ko le se nkan:

Ailera l’olorun ama lo ju

Fun ‘se nla re

5. Wa, ma sise

‘Simi ko si nigbat ‘ise osan

Titi orun yio fi wo l’ale

TI awa osi gbo ohun ni pe

“O seun omo”

6. Wa, ma sise

Lala na dun, ere re si daju.

‘Bukun f’awon t’o f’ori ti d’opin

Ayo won ‘simi won, y’o ti po to

‘Lod’ Oluwa!

Lyrics Submitted by Olasoju Taiwo

Enjoy the lyrics !!!